Inicio Top Música Bad Bunny Música Cristiana Taylor Swift Ed Sheeran Luis Fonsi Ozuna Daddy Yankee J Balvin Maluma DMCA

Letra de 'Tóótó' de Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band - Escucha y canta en New Musicas

Varios-artistas

90s Acoustic Hits

Varios-artistas

Retropop 90s

Varios-artistas

Viajar Con Bebes

Varios-artistas

Beethoven Recomposed

Artist profile picture

Tóótó

Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band

Canciones

Ẹni ma ba wa ṣe pọ, ìyẹn a b'ẹwu ana sọnù
A fi'wa tutu ṣ'aṣọ, a mọ tooto o
Ẹni ma ba wa jẹun agba, a ko'wa ibajẹ sọnù
A wa fọ'wọ rẹ, a mọ tooto o (tootoo-to o)

Olofofo, ẹgbẹ àwọn ọdaluru
Tẹmbẹlẹkun, awo ọlọtẹ o ni'ye
Adanikanjẹ, alainitẹlọrun
Wọn o ni le ba wa ṣe pọ
Wọn o ni le ba wa rin pọ
Wọn o ni le ba wa gbe pọ, rara

Ẹni ma ba wa rin pọ, ìyẹn a ko'wa ìdọtí sọnù
A gb'ẹsẹ s'ọna rere, a mọ tooto o
Ẹni ma ba wa jẹun agba, a ko'wa ibajẹ sọnù
A wa fọ'wọ rẹ, a mọ tooto o (tootoo-to o)

Ṣọtẹṣebí, olopurọ ọbayejẹ
Fibiṣẹwa, awo onibilisi
Alaimọra, ẹgbẹ onímọdaru
Wọn o ni le ba wa ṣe pọ
Wọn o ni le ba wa rin pọ
Wọn o ni le ba wa gbe pọ, rara

Ẹni ma ba to pọ, ìyẹn a fi'wa ẹtẹ silẹ
A wa tun'ra rẹ bi o, a mọ tooto o