Inicio Top Música Bad Bunny Música Cristiana Taylor Swift Ed Sheeran Luis Fonsi Ozuna Daddy Yankee J Balvin Maluma DMCA

Letra de 'Ise L'adura' de Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band - Escucha y canta en New Musicas

Varios-artistas

Pop Rewind

Varios-artistas

Manana tranquila

Varios-artistas

Indie Party

Varios-artistas

Top Hits 2015

Artist profile picture

Ise L'adura

Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band

Canciones

Iṣẹ mà l'àdúrà ẹni
Àgbà t'ó m'òye, ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ s'ọ'nà òtítọ
K'ọ'n lè ṣe're l'áyé
Ani, iṣẹ' yẹn làwúre gangan
Àgbà t'ó m'òye, ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ ní'wà gidi
K'ọ'n lè ṣe're l'áyé

Ẹni ńfẹ're l'óko
Ìyẹn á dẹ'lẹ' f'ọ'kà
Á t'èbù bọ'lẹ' l'ásìkò, á ro'ko, á kọ'bè
Ẹni ńwá èrè ọjà
Ìyẹn á k'óun sí'lẹ'
Á s'ẹ'rín, s'ọ'yàyà, á p'olówó, á f'oníbàárà mọ"ra

Sebi, iṣẹ' yẹn l'àdúrà ẹni
Àgbà t'ó m'òye, ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ s'ọ'nà òtítọ
K'ọ'n lè ṣe're l'áyé
Àní, iṣẹ' yẹn làwúre gangan
Àgbà t'ó m'òye, ẹ jọ'wọ', ẹ kọ'mọ ní'wà gidi
K'ọ'n lè ṣe're l'áyé

Ẹni ń wá ọrọ inú ibú
Ìyẹn á ti'kọ' s'ómi
Á s'àwọ'n s'ódò gbalaja, níbi t'áwọn ẹja pọ' rẹpẹtẹ
Ọlọ'dẹ àná ò f'ẹnu p'ẹran
Ńṣe ló gbé'ra ní'lẹ'
Tó wọ'nú aginjù láìbẹ'rù f'éwu tí ń bẹ l'ọ'nà o

Àní, iṣẹ' yẹn l'àdúrà ẹni
Àgbà t'ó m'òye, ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ s'ọ'nà òtítọ
K'ọ'n lè ṣe're l'áyé
Moni, iṣẹ' yẹn làwúre gangan
Àgbà t'ó m'òye, ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ ní'wà gidi
K'ọn lè ṣe're l'áyé

Fọwọ'pawọ' ngò rí ń kan (ṣ'iṣẹ', fi sùúrù si)

Fẹsẹ'pasẹ' ngò rí ń kan (ṣ'iṣẹ', fi òtítọ' si)

Tojúbọlé, ẹ o r'erè níbẹ' (ṣ'iṣẹ', fi sùúrù si)

Sẹbọṣòògùn òtúbántẹ' (ṣ'iṣẹ', fi òtítọ' si)

Jágbójájù, láìláròjinlẹ' (ṣ'iṣẹ', fi sùúrù si)

Ògbójúwòkè w'Elédùmarè (ṣ'iṣẹ', fi òtítọ' si)

Sebí'ṣẹ' yẹn l'àdúrà ẹni (ṣ'iṣẹ', fi sùúrù si)

Àní iṣẹ' yẹn l'àwúre gangan o (ṣ'iṣẹ', fi òtítọ' si)

Inicio Top Música Bad Bunny Música Cristiana Taylor Swift Ed Sheeran Luis Fonsi Ozuna Daddy Yankee J Balvin Maluma DMCA