Inicio Top Música Bad Bunny Música Cristiana Taylor Swift Ed Sheeran Luis Fonsi Ozuna Daddy Yankee J Balvin Maluma DMCA

Letra de 'Eye Mejila' de Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band - Escucha y canta en New Musicas

Varios-artistas

Indie Party

Varios-artistas

Top Hits 2011

Varios-artistas

Musica triste para llorar

Varios-artistas

Gospel Hits Internacionais

Artist profile picture

Eye Mejila

Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band

Canciones

Ẹyẹ méjìlá, l'órí igi, l'étí fèrèsé ilé mi
Wọn mí kọ'rin, l' òwúrọ' tí mo jí
Wọn mí kọ'rin ayọ

Wọn mí kọ'rin ìwúrí

Mo wá gbé'ra ní'lẹ', mo bọ'jú, bọ'nu
Mo gbé àpamọ'wọ' mi, mo kó bàtà s'ẹsẹ
Ojú mà mí ro mí, àárẹ m'ọ'kàn mi
Ẹyẹ ó dá'nu dúró o, wọn mí kọ'rin

Wọn mí kọ'rin ìgboyà

Wọn mí kọ'rin ìṣítí

Wọn ní
Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ
Ṣe kíá-kíá, yára bóóde, ire mà mí pè ọ o

Mo ṣí ilẹkùn ilé, mo bọ' s'óde
Mo rìn pàdé ẹbí, pẹ'l'álàdúgbò
Mo fi tẹ'rìtẹ'rìn kí gbogbo wọn

Mo mí kọ'rin ayọ

Mo mí kọ'rin ìwúrí

Mo mà d'óko òwò mi, mo wà ní'bi iṣẹ'
Mo pàdé ọdọ, mo mà r'ọmọdé níbẹ' o, pẹ'l'ágbàlagbà
L'ọ'kùnrin, l'óbìnrin
Mo r'ẹ'ni tí ń ronú, mo r'ẹ'ni tí ń bẹ'rù
Mo r'ẹni tí ń gbọn l'ẹsẹ, t'ó ń ṣiyèméjì
Ma fi sùúrù kẹ wọn, ma tọ wọn s'ọnà

Mo mí kọ'rin ìgboyà

Mo mí kọ'rin ìṣítí

Mo ní
Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ
Ṣe kíá-kíá, yára bóóde, ògo mà mí pè wá o

Ẹyẹ méjìlá, l'órí igi, l'étí fèrèsé ilé mi
Wọn mí kọ'rin, l'òwúrọ' tí mo jí
Wọn mí kọ'rin ayọ'

Wọn mí kọ'rin ìwúrí

Wọn ní
Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ
Ṣe kíá-kíá, yára bóóde o, ire mà mí pè ọ' o
Ṣe gírí, múra jáde o, òní mà ládùn púpọ
Wọn ni, Ṣé kíá-kíá, yára bóóde o, ogo wa mí pè wa o
Wọn ni, Ṣé gírí, múra jáde, múra jáde o, òní mà ládùn púpọ
Ṣe kíá-kíá, wọn ni, Yára bóóde, yára bóóde, ire mà mí pè ọ o
Wọn ní, wọn ni, Ṣé gírí, ani o múra jáde, múra jáde, òní mà ládùn púpọ
Ṣe kíá-kíá, ani o yára bóóde o, ogo wa mí pè wa o

Mura jade
Mura jade
Yára bóóde

Inicio Top Música Bad Bunny Música Cristiana Taylor Swift Ed Sheeran Luis Fonsi Ozuna Daddy Yankee J Balvin Maluma DMCA