Inicio Top Música Bad Bunny Música Cristiana Taylor Swift Ed Sheeran Luis Fonsi Ozuna Daddy Yankee J Balvin Maluma DMCA

Letra de 'Ẹ̀gún Nlá' de Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band - Escucha y canta en New Musicas

Varios-artistas

Carnaval Kids

Varios-artistas

Tarantino

Varios-artistas

Top Hits 2015

Varios-artistas

Sol Y Playa

Artist profile picture

Ẹ̀gún Nlá

Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band

Canciones

Ẹgun nla ni wa
Ṣonṣo ori wa o ṣe gun mọ'lẹ o
Atẹnimọlẹ kẹ ṣọ'ra
Kekere la kere
A o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo

Ìṣó nla ni wa
Ṣonṣo ori wa o ṣe gun mọ'lẹ o
Afojudini kẹ ṣọ'ra
Jẹjẹ la duro
A o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo

Aja ọdẹ n woye, wọn ṣe bo sun
Ọmọdé o mọ, o n f'aja ni'ru
Ẹ wa w'eyin gagara
Kiniun ni bi? Àmọtẹkun ni bi?
Tani o duro, tani o duro wo lẹẹmeji?
Boolọ, boolọ, yaa mi, boolọ

Ẹgun nla ni wa
Ṣonṣo ori wa o ṣe gun mọ'lẹ o
Atẹnimọlẹ kẹ ṣọ'ra
Kekere la kere
A o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo

Ẹẹgbẹ opurọ, aferugbabukun
Wọn n wọ gẹgẹrẹ
Wọn ṣe ba o ri wọn, wọn n wọ gẹgẹrẹ
Agba a dakẹ, a wo'ṣe ọdẹ
Ki ma ii ṣe ti'bẹru, ki i ṣe t'aigbọn
Alaṣeju ii gb'ẹbẹ o, iya ti o jẹ ni n wa kiri

Ìṣó nla ni wa
Ṣonṣo ori wa o ṣe gun mọ'lẹ o
Afojudini kẹ ṣọ'ra
Jẹjẹ la duro
A o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo

B'ẹ ri wa k'ẹ yọ mọ wa
B'ẹ ri wa k'ẹ yọ mọ wa
B'ẹ ri wa k'ẹ yọ mọ wa
K'ẹ mu eti igbọ, k'ẹ ko bata ijo
K'ẹ ke si gbogbo ẹbi at'ọrẹ, wa s'agbo idunnu
Onibajẹ bila, oniwaburuku, ronú rẹ ko piwada o
Ronu rẹ ko piwada o

Ẹgun nla ni wa
Ṣonṣo ori wa o ṣe gun mọ'lẹ o
Atẹnimọlẹ kẹ ṣọ'ra
Kekere la kere
A o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo

Ìṣó nla ni wa
Ṣonṣo ori wa o ṣe gun mọ'lẹ o
Afojudini kẹ ṣọ'ra
Jẹjẹ la duro
A o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
A o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
A o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
A o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
(A o ṣe gun mọ'lẹ o) a o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
(A o ma ṣe tẹ mọ'lẹ o) a o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
(A o ṣe gun mọ'lẹ o) a o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo

A o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
(A o ṣe gun mọ'lẹ o) a o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
(A o ṣe tẹ mọ'lẹ o) a o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
(A o ṣe gun mọ'lẹ o) a o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
(Ṣọ'ra o, e) a o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo
(Ṣọ'ra o, e) a o ṣe gun mọ'lẹ, ṣonṣo!

Inicio Top Música Bad Bunny Música Cristiana Taylor Swift Ed Sheeran Luis Fonsi Ozuna Daddy Yankee J Balvin Maluma DMCA